Ẹgbẹ́ Àjọ Iṣẹ́ Àgbáyé ITUC-Afrika, ti dá ẹ̀bi fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó dìtẹ̀ gbá-jọba ní Guinea-Bissau ní àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìpadàsẹ́yìn sí ìjọba tiwantiwa ní Áfíríkà.”
Ọ̀rọ̀ kán láti ọwọ́ Akọ̀wé Àgbà ITUC-Afrika, Comrade Joel Odigie, sọ pé Áfíríkà yẹ kó dúró ní ìṣọ̀kan kó sì dá “àwọn tó ń ló agbára làti gbá-jọba lọnà tí kò bá òfin mu ní kọ́ńtínẹ́ǹtì náà lẹ́bi.”
Ọ̀rọ̀ náà tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Dáàbò bo Ìlànà Òfin-Kò sí Ìdìtẹ̀ gbá-jọba Mọ́ ní Áfíríkà,” wọ́n sọ pé “Ẹgbẹ́ Àgbègbè Áfíríkà ti Àjọ Iṣẹ́ Àgbáyé (ITUC-Afrika dẹ́bi fún ìdìtẹ̀ gbá-jọba ní Orílẹ̀-èdè Guinea-Bissau gidigidi.”
