Ìpàdé Ìjọ Mùsùlùmí Ahmadiyya (Jalsa Salana) tí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ọdún 2026, ní a ti kéde láti ọwọ́ Òlùdarí àgbà ti ìjọ Mùsùlùmí Ahmadiyya, Hazrat Mirza Masroor Ahmad, Khalifatul Masih V.
Ìpàdé Jimat àti gbígbé àsìá sókè ní ọjọ́ Ẹtì kéde ìbẹrẹ ayẹyẹ náà ní ààyè àpéjọ Hadeeqatul Mahdi ni Alton, Hampshire, United Kingdom.

Olórí gbogbogbòò tí Mùsùlùmí Ahmadiyya nínú ọrọ ìbẹrẹ rẹ̀ pe àwọn Mùsùlùmí àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ahmadiyya láti ṣe àtìlẹ́yìn fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Islam, kí wọn mọ Allãh nínú gbogbo àwọn iṣe wọn. O pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn láti ṣe àwọn ìrúbọ pàtàkì sí Ọlọrun kí wọn si gbàdúrà gidigidi fún àwọn ohun réré ti ayé àti orún.
Ṣáájú ìfilọ́lẹ̀ ayẹyẹ náà, Olùdarí Ahmadiyya ṣe àbẹwò si ààyè Jalsa Salana UK ní Ọjọ́bọ̀ láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ètò àti bá àwọn olùyọ̀ǹda ara-ẹni tí n ṣíṣẹ́ sọrọ ní gbogbo wákàtí.

O tún lọ sí ìbi ìdáná oúnjẹ, títí kan ilé iṣẹ́ roti, ibi ìpa ẹran, ibi ìfọṣọ ìkòkò àti ilé ìtajà, ó wo bí gbogbo ẹ̀ka wọ̀nyí ṣe ń ṣiṣẹ́ dáadáa, ó sì bá àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ sọ̀rọ̀.
Lẹ́yìn náà, ó ṣe àyẹ̀wò ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfihàn, títí bí ìtọjú ọmọnìyàn, àtúntò ẹ̀sìn, Islam tòótọ tí UK, Ẹgbẹ́ Ayàwòrán Ile Gbogbogbòò tí Ahmadiyya àti Àwọn Onímọ̀ Ẹrọ, IAAAE, ITQA àti Ilé Ìkòwé pamọ́ àti iṣẹ́ ìwádìí ti Ahmadiyya, àti Al Hakam, èyí tó ṣe àfihàn àpẹẹrẹ Qadian ní ọdún yìí.

Ẹ máa hùwà rere nígbà gbogbo.
Lẹ́yìn èyí, Hazrat Khalifatul Masih Karùn-ún lọ sí orí pèpéle láti sọ ọ̀rọ̀ kúkúrú kan fún àwọn olùyọ̀ǹda ara-ẹni náà, ó rọ̀ wọ́n láti jẹ́ onínúure, onísùúrù àti oníwà rere bí wọ́n ti ṣe ní àwọn ọdún tó kọjá.
