Ilé-Iṣẹ́ Ìlera Ethiopia sọ pé kò tíì sí ìjábọ̀ m ẹnikẹ́ni tún ní àrùn Marburg láti ọjọ́ Ẹtì tó kọjá ní ìlú Jinka ní gúúsù Ethiopia, lẹ́yìn tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ènìyàn mẹ́fà ló kú latari àrùn náà.
Mínísítà Ìlera Ethiopia Mekdes Daba sọ fún àwọn oníròyìn pé àwọn ìsapá ìṣọ̀kan ń lọ lọ́wọ́ láti dá àwọn tó lè ti ní àrùn náà mọ̀ àti láti ya àwọn tó ti ní àrùn náà sọ́tọ̀.
Ìjọba Ethiopia jẹ́rìí sí i ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kọkànlá pé àrùn Marburg ti bẹ́ sílẹ̀ ní ìlú Jinka ní gúúsù Ethiopia. Èyí tẹ̀lé àyẹ̀wò yàrá ti àwọn àyẹ̀wò láti inú àwọn ènìyàn tí wọ́n fura sí pé wọ́n ní àrùn náà.
Èyí ní àkọ́kọ́ irú àrùn náà ní orílẹ̀-èdè Ethiopia.
Ilé Iṣẹ́ Àgbà fún Ìṣàkóso àti Ìdènà Àrùn Africa (Africa CDC) jẹ́rìí sí àrùn tó léwu náà ní ìlú Jinka.
Àwọn olùṣewádìí lórí àjàkálẹ̀ àrùn àti ìwádìí yàrá àwọn àrùn sí tí ń tẹ̀síwájú síí lọ́wọ́lọ́wọ́, àti pé ìwádìí sọ pé irú àrùn náà ní èyí tó wáyé ní apá Ìlà Oòrùn Africa, Africa CDC sọ nínú ìròyìn kan ní ìparí ọ̀sẹ̀ tó lọ́.
Àrùn Marburg ló jẹ́ kokoro arun tó ni àkóràn púpọ, o si yara paniyan ní kíákíá pẹ̀lú ibà ẹ̀jẹ. Àwọn ààmì àìsàn náà ní, iba giga ati orí-fífọ́ lílé, o màá ń hàn lára láàrin ọsẹ kán.
Ajọ Ìlera Àgbáyé (WHO) sọ pé o jẹ́ ọmọ ìdílé kòkòrò àrùn kànnà bí Ebola.
