Ẹgbẹ́ olùgbèjà kan tó wà ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti fi ẹ̀sùn kán ilé-iṣẹ́ Apple ní ilé-ẹjọ́ kan ní Washington lórí àwọn ohun alumọ́ọ́nì tó níí ṣe pẹ̀lú ìforígbárí àti ìlòkulò ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní Orílẹ̀-èdè Democratic Republic of Congo àti Rwanda èyí tí ilé-iṣẹ́ tó ń ṣe iPhone náà kọ.
Àwọn Agbẹjọ́rò Ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn Àgbáyé (IRAdvocates) ti fi ẹjọ́ kan àwọn ilé-iṣẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ yìí èyí tí Tesla Apple pẹ̀lú àti àwọn ilé-iṣẹ́ mìíràn lórí rírí ‘cobalt,’ ṣùgbọ́n ilé-ẹjọ́ Amẹ́ríkà dá ẹjọ́ náà nu-ú ní ọdún tó kọjá.
Àwọn agbẹjọ́rò Faransé náà tún fi ẹjọ́ Congo yìí sílẹ̀ ní Oṣù Kejìlá lórí ẹ̀sùn kan naa pẹ̀lú àìsí ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ sùgbọ́n ìwádìí n tẹsiwaju ní Orílẹ̀-èdè Belgium lórí ẹ̀sùn kán náà.
Apple kọ́ ẹ̀sùn Congo náà pẹ̀lú pé ó ti pàṣẹ fún àwọn olùpèsè rẹ̀ láti dáwọ́ wíwá àwọn ohun alumọ́ọ́nì ní Congo àti Rwanda tó wà ní àdúgbò rẹ̀ dúró.
