Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Goodluck Jonathan ti sọ fún Ààrẹ Nàìjíríà, Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu nípa ipò tí òṣèlú wá ní Guinea-Bissau.
Dókítà Jonathan, ẹni tí ó ṣe olórí Ìgbìmọ̀ Olùṣàyẹ̀wò Ìdìbò Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà (West African Elders Forum WAEF) sí Guinea-Bissau, sọ fún Ààrẹ Tinubu ní Ilé-ìṣẹ́-ìjọba ní Abuja, ní ọjọ́ Sátidé, ó sì fún un ní ìròyìn nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní orílẹ̀-èdè náà lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ológun gba ìjọba, èyí tí ó dá ìlànà ìdìbò dúró lójijì tó sì fa bí gbogbo àgbáyé ṣé ndá wọ́n lẹ́bi.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn ilé-iṣẹ́-ìjọba, Ààrẹ tẹ́lẹ̀ náà tẹnu mọ́ ọn pé ìdìbò Guinea-Bissau ti parí ní pàtàkì, pẹ̀lú kíkà àwọn àbájáde tó fẹ́rẹ̀ẹ́ parí kí àwọn ológun tó dá sí i kí wọ́n sì dá ìkéde náà dúró.
Dókítà Jonathan fi kún un pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò le yọ ológun kúrò pẹ̀lú agbára láì kó ewu ikú bá àwọn aráàlú, ECOWAS gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ ìbánisọ̀rọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pẹ̀lú ìjọba ológun kí wọ́n sì béèrè fún ìtúsílẹ̀ àwọn olóṣèlú tí wọ́n ti mú, títí kan olùdíje alátakò tí, ó sọ pé kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ kankan.
Ààrẹ tẹlẹ rí náà wá rọ awọn olori ECOWAS láti bá àwọn aláṣẹ ológun ní Guinea-Bissau s’ọrọ tààrà láti ríi dájú pé a kéde Olubori nínú ìdìbò orílẹ̀-èdè náà láìpẹ́ yìí.
O tẹnumọ pé a kò gbọdọ̀ bá àgbàrá àwọn ènìyàn aráàlú jẹ́.
