Ààrẹ tí wọ́n yọ kúrò ní Guinea-Bissau Umaro Sissoco Embalo ti dé sí Brazzaville, olú ìlú Republic of Congo, ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ológun gbá ìjọba, gẹ́gẹ́ bí orísun kan tí ó sún mọ́ ọn ṣé sọ.
Àwọn ọmọ ogun yọ́ Ààrẹ Embalo ní ọjọ́rú kí wọ́n tó kéde àbájáde ìdìbò Ààrẹ àti ti ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ìparí ọ̀sẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè tí wọ́n tí ń sọ èdè Portuguese.
Embalo ti kọ́kọ́ fi Bissau sílẹ̀ lọ sí Senegal pẹ̀lú ọkọ̀ òfurufú pàtàkì kan, bí àwọn ológun ṣe fi Major-General Horta Inta sí ipò Ààrẹ ní ọjọ́rú.
Orísun náà kó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa Embalo ní Brazzaville.
