New service chiefs
Nàìjíríà Yán Olórí Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun Túnt
Ààrẹ Bola Tinubu tí yán àwọn Olórí Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun túntún tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Gẹ́gẹ́ bí Olùdámọ̀ràn Pàtàkì fún Ààrẹ lórí Ìròyìn àti Ìbánisọ̀rọ̀ Gbogbogbò, Sunday Dare, àwọn Olórí Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun túntún náà ní, General Olufemi Oluyede tó rọ́pò General Christopher Musa gẹ́gẹ́ bí Olórí Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun túntún.

Major-General W. Shaibu ní Olórí Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun oríilẹ̀ túntún, nígbàtí Air Vice Marshall S. K. Aneke dí Olórí Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun òfurufú túntún, tí Rear Admiral I. Abbas dí Olórí fún Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun ojú-omí túntún.
Olórí Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun Ọtẹlẹmuyẹ, Major-General E.A.P. Undiendeye, dúró ní ipò rẹ̀ tẹlẹ.
Dare sọ nínú gbólóhùn náà pé: “Ààrẹ, Olórí Àgbà fún Àwọn Ọmọ-ogun, fi ọpẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sí àwọn Olórí Àgbà fún Àwọn Ọmọ-ogun tó kúrò ní ipò náà, Ọ̀gágun Christopher Musa àti àwọn akẹgbẹ rẹ̀, fún ìfẹ́ orílẹ̀-èdè àti ìdarí tó fìdí múlẹ̀ tí wọ́n ṣé.
“Ààrẹ pàṣẹ pé iṣẹ́ wọ́n tí bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí wọ́n sí ríi dájú pé wọ́n ṣiṣẹ́ tọ́ ìdánilójú ìgbẹ́kẹ̀lé tí Orílẹ̀-èdè yìí gbé lé wọ́n lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí Olórí Ọmọ-ogun tó kún ojú òṣùwọ̀n.
Remi Loko
