Egypt Yóò Ṣe ìfilọ́lẹ̀ Ilé Àkójọ Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Tuntun Fún Ìtúnṣe Àwọn Arìnrìn-àj
Àwọn aláṣẹ Orílẹ̀-èdè Íjíbítì (Egypt) ń retí kí ìfilọ́lẹ̀ ilé àkójọ àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé túntún kán tí wọ́n yóò kó jáde ní ọjọ́ Sátidé (Àbámẹ́ta) yóò mú kí ìtúnṣe ilé-iṣẹ́ ìrìnàjò tí àwọn rògbòdìyàn ìyípadà inú ilé, àjàkálẹ̀-àrùn, àti àwọn ìjà agbègbè tí dí lọ́wọ́ gbérú síi.
Àwọn aláṣẹ gbàgbọ́ pé Ilé Àkójọ àwọn Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Ńlá ti Íjíbítì náà nìkan le fa àwọn àlejò tó tó mílíọ̀nù méje síi lọ́dọọdún lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣí ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, èyí tí yóò mú kí iye àwọn àlejò tó tó ọgbọ̀n mílíọ̀nù pọ̀ sí i ní ọdún 2030.
Ní rírí àwọn ‘Pyramids Giza’, ilé náà tí ó tó mílíọ̀nù kán dín ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta onigun mẹrin mítà (500,000-square-metre) yóò ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn oun ìṣẹ̀ǹbáyé, títí kan oun tí a pè ní ìkójọpọ̀ gbogbo ìṣúra ọba Tutankhamun, tí wọ́n yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ́n hàn fún ìgbà àkọ́kọ́.
