Buratai Rọ́ Àwọn Ọmọ Ogun Ilẹ̀ Áfíríkà Láti Ṣé Àjọṣepọ̀ ÌdàgbàsókèOlórí Ọmọ-ogun Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ ríi,
Lieutenant General Tukur Buratai (rtd), tí ké sí àwọn Ọmọ-ogun Ilẹ̀ Áfíríkà láti ṣé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ológun àti ìbánisọ̀rọ̀ láìsí ìṣòro ní àsìkò àlàáfíà.
Ọgágun tó ti fẹ̀yìntì, tó tún ún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣojú Nàìjíríà sí Orílẹ̀-èdè Benin, sọ oún pàtàkì yìí gẹ́gẹ́ bí olùgbìmọ̀ràn pàtàkì níbi ìpàdé àwọn olórí ogun ilẹ̀ (LFCS) 2025 tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ní Kigali.

Ìpàdé gíga náà, tí ẹgbẹ́ ológun ààbò Rwanda (RDF) gbàlejò láti ogúnjọ́ sí ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹwàá, ọdún 2025.
Láti yanjú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, Olórí Ọmọ-ogun tẹ́lẹ̀ náà dábàá ọ̀nà ìṣètò sí ìbáramu, ó rọ ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun Ilẹ̀ Áfíríkà àti àwọn ẹgbẹ́ agbègbè bíi ECOWAS àti Àjọ Ìdàgbàsókè Gúúsù Áfíríkà (SADC) láti ṣe amọ̀nà fún ìṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́, ẹ̀kọ́, àti ohun èlò.
Lt. Gen. Buratai ti àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ náà ṣé déédé pẹ̀lú ọrọ ìbẹ̀rẹ̀ àpérò náà tí Ààrẹ Rwanda, Paul Kagame, ẹni tí ó pe àwọn Olórí Orílẹ̀-èdè Áfíríkà níjà láti wó àwọn ìdènà ìjọba lulẹ̀ kí wọ́n sì gbé àṣà tuntun ti ìbáṣepọ̀ ààbò ọgbọ́n lárugẹ.
Àpérò náà ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìdí pàtàkì fún ṣíṣe àgbékalẹ̀ àwọn ètò ìṣètò láti kojú àwọn àyípadà ààbò Áfíríkà, títí kan àwọn ìjíròrò lórí ogun duroonu àti àjọṣepọ̀ ààbò.
“Àpérò yìí jẹ́ àkókò tó yẹ àti pé ó ṣe pàtàkì gan-an,” Buratai parí ọ̀rọ̀ rẹ̀. “Ó ń pè wá níjà láti ronú ní ọ̀nà ọgbọ́n àti láti ṣiṣẹ́ papọ̀ láti mú àlàáfíà àti ìdúróṣinṣin pọ̀ sí i ní ilẹ̀ wa.”
LFCS jẹ́ ìjíròrò ààbò Ilẹ̀ Áfíríkà tó gbajúmọ̀ lọ́dọọdún tó ń kó àwọn olórí Ọmọ-ogun Áfíríkà àti àwọn Olórí ogun jọ láti jíròrò àwọn ohun pàtàkì ààbò, láti pa àwọn ìrírí iṣẹ́ pọ̀ àti láti mú kí ìbáṣepọ̀ ààbò lágbára sí i.
