Àwòrán ọgbọ̀n ìṣẹ́jú kan lórí iye àwọn oníròyìn tó kú ní Gaza ni wọ́n ti gbé jáde níbi ìpàdé ọdọọdún Ijọ Mùsùlùmí Ahmadiyya ti ọgọ́ta ọdún ní UK, Hadeeqatul Ahmad, Alton Hampshire, United Kingdom, pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Ìjáde àti Àjọṣepọ̀ Gbogbogbòò ti United Kingdom.
Ní ìkàsílẹ̀ ìkẹyìn, ó lé ní àádọ́talérùgba (250) Àwọn Oníròyìn ní Gaza tí Ọmọ-ogun Ísírẹ́lì ti pa gẹ́gẹ́ bí apá kan ìkọlù sí Hamas àti àwọn ènìyàn Palestine ní àwọn agbègbè tí wọ́n ti gbà.

Àkọlé fíìmù náà ni “GAZA IBOJÚ FÚN ÀWỌN ONÍRÒYÌN”, ‘AnalystNews’ ṣàfihàn rẹ̀ ni Ilé-ìgbìmọ̀ Gbogbo Oníròyìn Àgbáyé (International Press and Media Center) ní ọjọ́ ìkẹyìn ìpàdé àwọn Ahmadiyya naa.
![]()
Ìfihàn náà jẹ́ oun ìrora àti ìrírí ìbànújẹ́ fún Àwọn Oníròyìn ní Gaza. Ó fi àwọn òtítọ́ hàn kedere pé àwọn oníròyìn púpọ̀ ni wọ́n ti pa ní Gaza ju nínú ìjà èyíkéyìí nínú ìtàn òde òní lọ — síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn wọn, àti ìdákẹ́jẹ́ẹ́ tó jẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀, ní àwọn alágbára ayé tó ùn rí bí alairi i.
