Olórí Gbogbogbòò ti Ìjọ Àwọn Ahmadiyya Mùsùlùmí, Hazrat Mirza Masroor Ahmad, Khalifatul Masih Karùn-ún, ti gbé ìròyìn onítẹ̀síwájú ọdọọdún ti Àwùjọ Àwọn Mùsùlùmí Ahmadiyya kalẹ̀ fún ọdún 2026.
Ìgbékalẹ̀ náà ni a ṣe níbi ìpàdé ọdọọdún ti ọgọ́ta ọdún ti Ẹ̀sìn Islam (Jalsa Salana) ti ìjọ Àwọn Mùsùlùmí Ahmadiyya ti orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì, ní Hadeeqatul Mahdi, Alton, Hamshire, London, tí àwọn olùkópa àti àlejò tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta.
Gẹ́gẹ́ bí olórí àgbà Ahmadiyya ti sọ, ìròyìn rere tó sọ̀rọ̀ nípa ìtànkálẹ̀ Ẹ̀sìn Islam nípa ìtumọ̀ Al-Quran Mímọ́ ní èdè ìbílẹ̀ àti ti àgbáyé, kíkọ́ àwọn mọ́sálásí tuntun, ṣíṣí àwọn ilé ìtajà tuntun fún àwùjọ Ahmadiyya kárí ayé, pípín àwọn ìwé Islam àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tuntun mìíràn nínú àwùjọ Islam.

Gẹ́gẹ́ bí olórí Ahmadiyya náà, Hazrat Masroor Ahmad, ṣe sọ, “ìkéde Islam Ahmadiyyat ń tẹ̀síwájú láti dé gbogbo igun ayé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, ìrúbọ, àti àdúrà. Láti àwọn mọ́sálásí tuntun àti àwọn ilé iṣẹ́ ìránṣẹ́ títí dé àwọn mílíọ̀nù ìwé tí a pín káàkiri àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tó dara pọ̀ mọ́ Àwùjọ, ìwọ̀nyí kìí ṣe nọ́mbà lásán—wọ́n jẹ́ àmì ìbùkún Allah”.
