Minaret-University-1kirun
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke, Sultan tí Sokoto, Olórí ìgbìmọ̀ aṣòfin àwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí, Alhaji Saad Abubakar ati Ọọ̀ni ilé-ifẹ̀, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi II, ní wọn tí ṣètò láti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ àti ẹni tí yóò máa dárí ètò ilé ẹ̀kọ́ gíga náà tí wọ́n gbé kalẹ̀ ní Ìkìrun, Ìpínlẹ̀ Osun, Ìwọ̀-oòrùn, Nàìjíríà.
Gẹgẹ bí àlàyé kan láti ọdọ Qasim Akinreti, tó jẹ́ agbẹnusọ àti adari ìròyìn tí Ìjọ Ahmadiyya Muslim Jamaat ní Nàìjíríà, Ó ní, ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ tí Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Minaret, Ikirun àti iṣéfihàn adarí ètò àkọ́kọ́ tí ilé-ẹ̀kọ́ náà ní yóò wáyé ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ karùn-ún oṣù Kejì, ọdún yìí ní gbangan kékeré kan ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà tó jẹ́ tí ‘Global Ahmadiyya Muslim Community’.

Amir, Ahmadiyya Muslim Jamaat ti Nàìjíríà ati Alága àti Olùdarí Yunifásítì Minaret, Barrister Alatoye Azeez Folorunso, yóò ṣe àfihàn igbákejì Adarí rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Abdul Rahman Abdullah sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà àti àwọn ènìyàn ìlú Ìkìrun tó jẹ́ agbalejo.
