Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu tí gbóríyìn fún Àwọn Ọmọ-ogun Nàìjíríà fún dídúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí olùdáàbòbò àti olùgbèjà fún ìjọba tiwantiwa, lẹ́yìn ipá wọ́n nínú mímú ìlànà ètò òfin padà sípò ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Benin ní ọjọ́ Àìkú.
Ààrẹ nínú ìkéde kán tí Agbẹnusọ rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Bayo Onanuga fí síta ní ọjọ́ Àìkú, sọ pé iṣẹ́ àṣeyọrí náà fí ìdúróṣinṣin Nàìjíríà hàn sí dídáàbòbò ìṣàkóso Ìjọba tiwantiwa ní gbogbo agbègbè ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà (West Africa).
Ọ̀gbẹ́ni Onanuga ṣàlàyé pé “ìjọba Nàìjíríà dáhùn sí ìbéèrè méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Orílẹ̀-èdè Olómìnira Benin, èyí ló mú kí Ààrẹ Tinubu kọ́kọ́ darí àwọn ọkọ̀ òfurufú jagunjagun tí Nàìjíríà láti dáàbò bo ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́ orílẹ̀-èdè náà.”
Ó sọ pé àwọn ọkọ̀ òfurufú náà ni a gbé kalẹ̀ láti lé àwọn adìtẹ̀ Gbà’jọba tí wọ́n ti gbá ibùdó tẹlifíṣọ̀n Orílẹ̀-èdè náà tí wọ́n sì tún kó ara wọn jọ ní àgọ́ ológun.
Agbẹnusọ Ààrẹ sọ pé Orílẹ̀-èdè Benin, nípasẹ̀ Ilé-iṣẹ́ Àjọ Ilẹ̀-òkèèrè wọ́n, nínú ìwé ìránṣẹ́, béèrè fún ìrànlọ́wọ́ lójúkan náà fún ọkọ̀ òfúrufú Nàìjíríà “nítorí ìkánjú àti àìṣe pàtàkì ipò náà àti láti dáàbò bo ìlànà òfin tí ìjọba tiwantiwa, láti dáàbò bo àwọn ilé-iṣẹ́ orílẹ̀-èdè náà àti láti rí i dájú pé àwọn ènìyàn wà ní ààbò to péye.”
