Igbákejì Ààrẹ Kashim Shettima tí gbéra ní Abuja lọ́ sí Abidjan, Côte d’Ivoire, láti ṣojú fún Ààrẹ Bola Tinubu níbi ìfilọ́lẹ̀ Ọ̀gbẹ́ni Alassane Ouattara fún ìgbà kẹrin gẹ́gẹ́ bí olórí orílẹ̀-èdè náà.
A retí pé Igbákejì Ààrẹ Shettima yóò dara pọ̀ mọ́ àwọn aṣáájú mìíràn láti gbogbo Áfíríkà àti àwọn mìíràn láti rí àwọn ìgbòkègbodò tí a ṣètò fún ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹjọ oṣù Kejìlá ọdún 2025, ní Ààfin Ààrẹ ní Abidjan.

Wọ́n yan Ouattara fún ìgbà kẹrin ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 2025 gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Côte d’Ivoire, orílẹ̀-èdè kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà tó ní àjọṣepọ̀ oníṣọ̀kan pẹ̀lú Nàìjíríà.
