ECOWAS Logo
Aláṣẹ Àwọn Olórí Ìpínlẹ̀ àti Ìjọba ECOWAS, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ Ìgbìmọ̀ ìjíròrò àti Ààbò ECOWAS, ti dá Guinea-Bissau dúró kúrò nínú gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ìpinnu ECOWAS títí tí wọ́n fi dá ètò òfin tó péye padà ní orílẹ̀-èdè náà.
Nínú ìpàdé kan ní ìpele àwọn Olórí Ìpínlẹ̀ àti Ìjọba, tí Ààrẹ Sierra Leone, Julius Maada Bio, ṣe alága rẹ̀, àwọn olórí náà fi èròngbà wọ́n hàn lórí ìṣòro ìṣèlú tó ń ṣẹlẹ̀ ní Guinea-Bissau.
Abọ̀ ìpàdé náà sọ pé àwọn aráàlú ṣẹ̀ṣẹ̀ fí àníyàn wọ́n hàn sí ìjọba tiwantiwa nípa kíkópa nínú ìdìbò Ààrẹ àti Ìgbìmọ̀-Aṣòfin tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kọkànlá ọdún 2025.
Ìgbìmọ̀ ìjíròrò àti Ààbò ECOWAS bú ẹnu àtẹ lú ìfipágbàjọba tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 2025 pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó lágbára jùlọ, wọ́n sì pè fún àtúnṣe ìlànà òfin láìsí ìdíwọ́.
